Hymn 239 Kini ’simi ayo ailopin ni Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Kini ’simi ayo ailopin ni,
T’ awon angel at’ awon mimo ni?
’Simi f’ alare; f’ awon asegun,
Nibe l’ Olorun je ohun gbogbo.
2 ’Tal’ Oba na? tani yi ’te Re ka?
Irora itura Re ha ti ri?
So funni, enyin ti njosin nibe:
So funni, b’ oro to t’ayo nyin so.
3 Jerusalem toto, ilu mimo,
Alafia eyit’ o je kik’ ayo;
A r’ ohun t’a nfe n’nu re k’a to wi,
A si rigba ju eyit’ a nfe lo.
4 L’ agbala Oba wa, wahala tan,
Laiberu l’a o ma korin Sion;
Oluwa, niwaju Re lao ma fi
Idahun ’fe han f’ ebun ife Re.
5 ’Simi ko le tele ’Simi nibe:
Enikan ni ’Simi ti nwoju Re.
Nibe orin jubeli ko le tan,
T’ awon mimo at’ angeli y’o ko.
6 L’ aiye yi, pelu ’gbagbo at’ adua,
L’ ao ma saferi ’le Baba ohun;
Si Salem l’awon ti a si nipo
Npada lo; lat’ ilu Babiloni.
7 Nje awa teriba niwaju Re,
T’ Eniti ohun gbogbo jasi;
Ninu eniti Baba at’ Omo,
T’ Eniti Emi je Okanso lai. Amin.
