Hymn 238 Oluwa wa orun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa wa orun!
Ago re laiye yi,
Ibugbe ife re,
Ewa re ti po to!
Okan mi nfa
Lati goke
S’ ibugbe Re,
Olorun mi.
2 Ayo b’awon tin sin,
Nibiti’ Olorun yan;
Ti nwon npara ibe,
Lati ma josin won;
Nwon nyin O sa;
Ayo b’awon
T’o fe ona
Oke Sion.
3 Lati ipa de ‘pa
Laiye osi wa yi;
Titi nwon fi goke,
Ti nwon si yo s’ orun:
‘Bugbe ogo!
‘Gbat’ Olorun
Ba m’ ese wa
De ibe na.
4 Olorun l’asa wa,
Imole at’ odi;
Owo re kun f’ ebun
A ngba ‘bukun nibe:
Ayo pupo
Ni fun awon
T’ o gbekele
Olorun wa. Amin.