Hymn 236 Hossana si Oluwa wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Hossana si Oluwa wa!
Hossana si Jesu Oba!
Si Eleda, Olugbala,
K’aiye, k’orun ko Hossana:
Ko Hossana: “Hossana loke orun.”
2 Hossana l’orin Angeli,
Hossana l’orin ti a ngbe;
L’oke, nisale, yi wa ka,
Oku at’ aye ngbe ’rin na :
Ko Hossona: “Hossana loke orun.”
3 Olugbala ti ntoju wa,
Pada wa ’le adura yi;
A pejo ni oruko Re,
Mu ileri Re se si wa:
Ko Hossana: “Hossana loke orun.”
4 Sugbon, bori ohun gbogbo,
Fi Emi Re kun okan wa,
Ki okan wa je ibugbe
Mimo ati yiye fun O:
Ko Hossana: “Hossana loke orun.”
5 L’ojo k’ehin, ojo eru,
T’aiye on orun o koja,
Awon ti a ti rapada,
Y’o tun gbe orin iyin na:
Ko Hossana: “Hossana loke orun.” Amin.
