Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 230 B’ elese s’ owo po Lyrics

Hymn 230 B’ elese s’ owo po Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 B’ elese s’ owo po,
Ti nwon nde s’ Oluwa,
Dimo si Kristi Re,
Lati gan Oba na,
B’ aiye sata,
Pelu Esu,
Eke ni nwon,
Nwon nse lasan.

2 Olugbala joba!
Lori oke Sion;
Ase ti Oluwa
Gbe Omo Tire ro:
Lati boji
O ni, k’ O nde,
K’ O si goke,
K’ O gba ni la.

3 F’ eru sin Oluwa,
Si bowo f’ ase Re;
F’ ayo wa sodo Re,
F’ iwariri duro;
E kunle fun,
K’ e teriba;
So t’ ipa Re,
Ki Omo na. Amin.

Exit mobile version