Hymn 229 Jesu t’o ku, k’ o gb’ aiye la Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Jesu t’o ku, k’ o gb’ aiye la,
Jinde kuro ninu oku,
Nipa agbara Re;
A da sile lowo iku,
O d igbekun n’ igbekun lo,
O ye, k’ o ma ku mo.
2 Enyin om’ Olorun, e wo
Olugbala ninu ogo;
O ti segun iku:
Ma banuje, ma beru mo,
O nlo pese aye fun nyin,
Yio mu nyin lo ’le.
3 O f’ oju anu at’ ife
Wo awon ti O ra pada;
Awon ni ayo Re;
O ri ayo at’ ise won,
O bebe kin won le segun,
Ki nwon ba joba lai. Amin.
