Hymn 223 “Kabo, ojo rere,” l’ao ma wi titi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 “Kabo, ojo rere,” l’ao ma wi titi;
A sete ’ku loni, Orun di ti wa.
’Wo Oku d’ alaye, Oba tit’ aiye!
Gbogb’ eda Re Jesu, ni nwon njuba Re.
“Kabo, ojo rere,” lao ma wi titi;
A sete ’ku loni, orun di ti wa.
2 Eleda, Oluwa, Emi alaye!
Lat’ orun l’ o ti bojuwo ’sina wa,
Om’ Olorun papa ni ’Wo tile se,
K’ O ba le gba wa la, O di enia.
“Kabo, ojo rere,” &c.;
3 ’Wo Oluwa iye, O wa to ’ku wo;
Lati f’ipa Re han, O sun n’ iboji;
Wa, Eni Oloto, si m’oro Re se,
Ojo keta Re de, jinde Oluwa!
“Kabo, ojo rere,” &c.;
4 Tu igbekun sile, t’ Esu de l’ewon,
Awon t’o si subu, jog be won dide;
F’ojurere Re han, je k’aiye reran.
Tun mu ’mole wa de, ’Wo sa ni ’mole;
“Kabo, ojo rere,” l’ao ma wi titi;
A sete ’ku loni, orun di ti wa. Amin.
