Hymn 220 Lo so fun gbogbo aiye Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Lo so fun gbogbo aiye,
Lo tan ihin ayo yi;
Eti t’ o ba gbo, y’o si,
Okan t’ o ba gbo, y’o la.
2 Jesu Olugbala wa,
T’ a sin, fi boji sile;
Olorun gba ebo Re,
Ebo ese araiye.
3 O ji lati ma ku mo,
Akobi awon t’o sun;
Eniti o ba gba gbo
Yio ye, b’ o tile ku.
4 Angeli! eda orun,
E ba araiye gberin;
Jesu Oludande ji,
Alafia titi lai. Amin.