Hymn 22 Jesu, bukun wa k’ a to lo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Jesu, bukun wa k’ a to lo:
Gbin oro Re si aiya wa;
K’o si mu k’ ife gbigbona
Kun okan ilowowo wa;
Nigba iye at’ iku wa,
Jesu, jare, se ’mole wa.
2 Ile ti su, orun ti wo;
’Wo si ti siro iwa wa;
Die n’ isegun wa loni
Isubu wa l’o papoju:
Nigba iye ati, &c.;
3 Jesu, dariji wa: fun wa
L’ ayo, ati eru mimo,
At’ okan ti ko l’ abawon
K’ a ba le jo O l’ ajotan:
Nigba iye ati, &c.;
4 Lala dun, ’tor’ Iwo se ri;
Aniyan fere, O se ri;
Ma je k’ a gbo t’ ara nikan
K’ a ma bo sinu idewo.
Nigba iye ati, &c.;
5 A mbe O f’ awon alaini,
F’ elese at’ awon t’ a fe;
Je ki anu Re mu wa yo,
’Wo Jesu, l’ ohun gbogbo wa.
Nigba iye ati, &c.;
6 Jesu, bukun wa, – ile su;
Tikalare wa ba wag be:
Angel’ rere nso ile wa;
A tun f’ ojo kan sunmo O.
Nigba iye ati, &c.; Amin.