Hymn 219 Jesu ye; titi aiye Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Jesu ye; titi aiye
Eru iku ko ba ni mo;
Jesu ye; Nitorina
Isa oku ko n’ ipa mo.
Alleluya!
2 Jesu ye; lat’ oni lo,
Iku je ona si iye;
Eyi y’o je ’tunu wa,
’Gbat’ akoko iku ba de.
Alleluya!
3 Jesu ye; fun wa l’ o ku,
Nje Tire ni a o ma se;
A o f’ okan funfun sin,
A o f’ ogo f’ Olugbala.
Alleluya!
4 Jesu ye; eyi daju,
Iku at’ ipa okunkun
Ki y’o le ya ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu.
Alleluya!
5 Jesu ye; gbogbo ’joba
L’ orun, li aiye, di Tire;
E je ki a ma tele,
Ki a le joba pelu Re.
Alleluyah! Amin.