Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 212 ’Wo t’ o mbebe f’ ota Re Lyrics

Hymn 212 ’Wo t’ o mbebe f’ ota Re Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 ’Wo t’ o mbebe f’ ota Re,
L’ or’ igi agbelebu:
Wipe, “fiji won Baba:”
Jesu, sanu fun wa.

2 Jesu, jo bebe fun wa,
Fun ese wa gbagbogbo;
A ko mo ohun t’ a nse:
Jesu, sanu fun wa.

3 Je k’ awa ti nwa anu,
Dabi Re l’ okan n’ iwa,
’Gbat’ a ba se wa n’ibi:
Jesu, sanu fun wa.

4 Jesu, ’Wo t’ o gbo aro
Ole t’ o ku l’egbe Re,
T’ o si mu d’ orun rere:
Jesu, sanu fun wa.

5 Ninu ebi ese wa,
Je k’ a toro anu Re,
K’ a ma pe oruko Re:
Jesu, sanu fun wa.

6 Ranti awa ti nrahun,
T’ a nwo agbelebu Re;
F’ ireti mimo fun wa,
Jesu, sanu fun wa.

7 ’Wo t’ o fe l’ afe dopin
Iya Re t’ o nkanu Re,
Ati ore Re owon:
Jesu, sanu fun wa.

8 Je k’ a pin n’nu iya Re,
K’ a ma ko iku fun O,
Je k’ a ari toju Re gba:
Jesu, sanu fun wa.

9 Ki gbogbo awa Tire
Je omo ile kanna;
’Tori Re, k’ a f era wa:
Jesu, sanu fun wa.

10 Jesu, ’Wo ti eru mba,
’Gbat’ o si ku ’Wo nikan,
Ti okunkun su bo O:
Jesu, sanu fun wa.

11 ’Gbati a ba npe lasan,
T’ ire wa si jina;
N’nu okun na di wa mu:
Jesu, sanu fun wa.

12 B’ o dabi Baba ko gbo,
B’ o dabi ’mole ko si,
Je k’ a f’igbagbo ri O,
Jesu, sanu fun wa.

13 Jesu, ninu ongbe Re,
Ni ori agbelebu,
’Wo ti o few a sibe:
Jesu, sanu fun wa.

14 Ma kongbe fun wa sibe,
Sise mimo l’ ara wa;
Te ife Re na l’ orun;
Jesu, sanu fun wa.

15 Je k’ a kongbe ife Re,
Ma samona wa titi,
Sibi omi iye ni;
Jesu, sanu fun wa.

16 Jesu Olurapada,
’Wo t’ se ’fe Baba Re,
T’ o si jiya ’tori wa;
Jesu, sanu fun wa.

17 Gba wa l’ ojo idamu,
Se oluranlowo wa,
Lati ma t’ ona mimo;
Jesu, sanu fun wa.

18 F’ imole Re s’ona wa,
Ti y’o ma tan titi lai,
Tit’ ao fi de odo Re:
Jesu, sanu fun wa.

19 Jesu, gbogbo ise Re,
Gbogbo ijamu Re pin;
O jow’ emi Re lowo;
Jesu, sanu fun wa.

20 ’Gbat’ iku ba de ba wa,
Gba wa lowo ota wa;
Yo wa ni wakati na;
Jesu, sanu fun wa.

2 1. Ki iku at’ iye Re,
Mu ore- ofe ba wa,
Ti yio mu wa d’ oke:
Jesu, sanu fun wa. Amin.

Exit mobile version