Hymn 210 Enyin ti nkoja Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Enyin ti nkoja,
Ya sodo Jesu:
O s’asan fun nyin bi, pe ki Jesu ku?
2 Alafia nyin:
Onigbowo nyin:
Wa wo bi banuje kan ri bayi ri.
3 Oluwa n’ jo na,
N’ ibinu Re gbe
Ese nyin l’ Odagutan, O ko won lo.
4 O ku, k’ o s’ etu
Nitor’ ese nyin:
Baba se Omo Re n’ ise ’tori nyin.
5 K’ a gb’ ore- ofe
Irapada mu,
Fun eni t’ o jiya t’o ku nipo wa.
6 Nigb’ aiye ba pin
Awa o ma bo
Ife titobi na, ti ki tan lailai. Amin.