Hymn 209 Ife lo to bayi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ife lo to bayi!
Ohun gbogbo pari,
O ti pari gbogbo ise
T’o tori re w’aiye.
2 Ohun ti Baba fe,
Ni Jesu ti se tan:
Wahala ati iya Re
Mu Iwe Mimo se;
3 Ko s’irora wa kan,
Ti Jesu ko je ri;
Gbogbo edun at’ aniyan,
L’okan Re siti mo.
4 L’ori t’a f’egun de,
At’okan Re mimo,
L’a ko gbogbo ese wa le,
K’O ba le wo wa san.
5 Ife lo mu K’o ku
Fun emi otosi;
’Wo Etutu f’ese gbogbo,
Mo f’igbagbo ro mo.
6 Nigba aini gbogbo,
Ati n’ite ’dajo,
Jesu, ododo Re nikan,
Ni igbekele mi,
7 Jo, sise ninu mi,
Bi O ti se fun mi,
Si je ki ife mi si O,
Ma fi ore Re han. Amin.