Hymn 200 Ogo ni fun Jesu Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ogo ni fun Jesu
T’o f’ irora nla
Ta eje Re fun mi
Lati iha Re.
2 Mo r’ iye ailopin
Ninu eje na;
Iyonu Re sa po,
Ore re ki tan.
3 Ope ni titi lai,
F’ eje ’yebiye
T’o ra aiye pada,
Kuro n’nu egbe.
4 Eje Abel’ nkigbe
Si orun f’esan;
Sugb’ eje Jesu nke
Fun ’dariji wa.
5 Nigbati a bu won
Okan ese wa,
Satan, n’ idanu re,
F’ eru sa jade.
6 Nigbat’ aiye ba nyo,
T’o ngbe ‘’yin Re ga,
Awon ogun Angel
A ma f’ayo gbe.
7 Nje, e gbohun nyin ga,
Ki iro na dun!
Kikan lohun goro,
Yin Odagutan. Amin.