Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 2 Ninu gbogbo ewu oru Lyrics

Hymn 2 Ninu gbogbo ewu oru Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ninu gbogbo ewu oru,
Oluwa l’ o so mi;
Awa si tun ri ’mole yi
A tun te ekun ba.

2 Oluwa, pa wa mo l’ oni,
Fi apa Re so wa;
Kiki awon ti ’wo pamo,
L’ o nyo ninu ewu.

3 K’ oro wa, ati iwa wa
Wipe, Tire l’ awa;
Tobe t’ imole otito
Le tan l’ oju aiye.

4 Ma je k’ a pada lodo Re,
Olugbala owon:
Titi a o f’ oju wa ri
Oju Re li opin. Amin.

Exit mobile version