Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 196 Hosanna s’Omo Dafidi Lyrics

Hymn 196 Hosanna s’Omo Dafidi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 “Hosanna s’Omo Dafidi:”
Hosanna! e korin!
“Olubukun l’eniti mbo
Loruko Oluwa.”

2 “Hosanna s’Omo Dafidi:”
L’egbe Angeli nke;
Gbogb’ eda, e jumo gberin,
Hosonna s’Oba wa.

3 Hosanna! awon Heberu
Ja im’ope s’ona ;
Hosanna! a mu ebun wa
Fi tun ona Re se.

4 T’agba t’ewe nke, Hosanna!
K’ijiya Re to de;
L’oni, a si nko Hosanna!
B’o ti njoba loke.

5 B’o ti gba ’yin won nigbana,
Jo, gba ebe wa yi!
Lorun, k’a le b’Angel korin,
Hosanna s’Oba wa. Amin.

Exit mobile version