Hymn 194 Gbogb’ ogo, iyin, ola Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Gbogb’ ogo, iyin, ola,
Fun O, Oludande,
S’ eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!
‘Wo l’ Oba Israeli,
Om’ Alade Dafid,
T’ O wa l’ Oko Oluwa,
Oba Olubukun.
Gbogb’ ogo, iyin, ola,
Fun O, Oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun.
2 Egbe awon maleka
Nyin O loke giga;
Awa at’ eda gbogbo
Si dapo gberin na.
Gbogb’ ogo, iyin, ola, &c.;
3 Awon Hebru lo saju,
Pelu imo ope:
Iyin, adua, at’ orin,
L’ a mu wa ‘waju re.
Gbogb’ ogo, iyin, ola, &c.;
4 Si O saju iya Re,
Nwon korin iyin won:
‘Wo t’ a gbega nisiyi,
L’ a nkorin iyin si.
Gbogb’ ogo, iyin, ola, &c.;
5 ‘Wo gba orin iyin won:
Gb’ adura t’ a mu wa,
‘Wo ti nyo s’ohun rere,
Oba wa Olore.
Gbogb’ ogo, iyin, ola, &c.Amin;.
