Hymn 188 Olorun, Baba mi, ’Wo npe Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olorun, Baba mi, ’Wo npe
Asako omo Re mora ?
Iwo o ha dariji mi ?
Mo de, mo de, jo gba mi la.
2 A ! Jesu, Iwo nrekoja
Pelu ore at’ agbara ?
’Wo ko ha ngbo igbe mi bi ?
Mo de, mo de, sanu fun mi.
3 A ! Emi Mimo, Iwo ni ?
Ore ti mo ti sati pe !
’Wo ha mbebe fun mi sibe ?
Mo de, mo de, m’ ailera le.
4 Mo de, Oluwa, ife Re
Ni o nro mi t’o si nfa mi:
Mo wole lese Re, ki mmo
B’o ti dun lati je Tire. Amin.
