Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 183 Gbogbo eje eran Lyrics

Hymn 183 Gbogbo eje eran Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Gbogbo eje eran,
Ti pepe awon Ju;
Ko le f’ okan l’ Alafia,
Ko le we eri nu.

2 Kristi Od’ agutan,
M’ ese wa gbogbo lo;
Ebo t’ o ni oruko nla,
T’ o ju eje won lo.

3 Mo f’ igbagbo gb’ owo
Le ori Re owon:
B’ enit’ o ronupiwada,
Mo jewo ese mi.

4 Okan mi npada wo
Eru t’ Iwo ti ru;
Nigbati a kan O mo ’gi.
Ese re wa nibe.

5 Awa nyo ni ’gbagbo,
Bi egun ti kuro;
Awa nyin Odo- agutan,
A nkorin ife re. Amin.

Exit mobile version