Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 18 Baba, a tun pade l’oko Jesu Lyrics

Hymn 18 Baba, a tun pade l’oko Jesu Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Baba, a tun pade l’oko Jesu,
A si wa teriba lab’ ese Re:
A tun fe gb’ ohun wa soke si O
Lati wa anu, lati korin ’yin.

2 A yin O fun itoju ’gbagbogbo,
Ojojumo l’ a~o ma rohin ’se re;
Wiwa laye wa, anu Re ha ko?
Apa Re ki o fi ngba ni mora?

3 O se ! a ko ye fun ife nla Re,
A sako kuro lodo Re poju;
Sugbon kikankikan ni O si npe;
Nje, a de, a pada wa le, Baba.

4 Nipa oko t’ o bor’ ohun gbogbo,
Nipa ife t’ o ta ’fe gbogbo yo,
Nipa eje ti a ta fun ese,
Silekun anu, si gbani si le. Amin.

Exit mobile version