Hymn 175 Otosi elese, e wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Otosi elese, e wa,
Wa ni wakati anu;
Jesu setan lati gba nyin,
O kun f’ anu at’ ife:
O si le se, o mura tan, ma foiya.
2 Enyin alaini, e wa gba
Ogo Olorun lofe,
’Gbagbo toto, ’ronu toto,
Or’ofe ti o nfa wa,
Wa ’do Jesu, laini owo, sa wa ra.
3 Ma je k’ okan nyin da nyin ro,
Maser o ti aiye nyin;
Gbogbo yiye t’ O mbere ni,
Ki e sa mo aini nyin:
’Yi l’ O fun nyin; ’tansan Emi l’ okan.
4 Eyin t’eru npa, t’are mu,
T’ e sonu t’e si segbe,
Bi e duro tit’ eo fi, san
E ki yio wa rara:
F’ elese ni, On ko wa f’olododo.
5 Olorun goke l’awo wa,
O nfi eje Re bebe:
Gbe ara le patapata:
Ma gbekele ohun mi:
Jesu nikan l’o le s’ elese l’ore.
6 Angeli at’ awon mimo
Nkorin ’yin Odagutan;
Gbohungbohun Oruko Re
Si gba gbogbo orun kan:
Halleluya ! elese le gberin na. Amin.
