Hymn 164 ’Wo t’ o ku ni Kalfari Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 ’Wo t’ o ku ni Kalfari,
’Wo t’ o mbebe f’ elese,
Ran mi lowo nigb’ aini;
Jesu, gbo ’gbe mi.
2 Ninu ibanuje mi,
At’ okan aigbagbo mi,
Em’ olori elese
Gb’ oju mi si O.
3 Ota lode, eru n’nu,
Ko s’ ire kan lowo mi,
Iwo l’ o ngb’ elese la,
Mo sa to O wa.
4 Awon miran dese pe,
Nwon si ri igbala gba,
Nwon gbo ohun anu Re,
Mu mi gbo pelu.
5 Mo k’ aniyan mi le O,
Mo si ngbadua si O,
Jesu, yo mi n’nu egbe,
Gba mi, ki mma ku.
6 ’Gbati wahala ba de,
Nigb’ agbara idanwo,
Ati lojo ikehin,
Jesu, sunmo mi. Amin.