Hymn 163 Oluwa, b’ agbowode ni Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa, b’ agbowode ni,
Mo gb’ okan mi le O;
Oluwa, f’ ore- ofe wi,
K’ o se anu fun mi.
2 Mo lu aiduro aiya mi,
Ekun at’ irora;
K’ o gb’ okan mi ’nu irora,
K’ o se anu fun mi.
3 N’itiju mo jew’ ese mi,
Jo fun mi n’ ireti;
Mo be, ’tori eje Jesu,
K’ o se anu fun mi.
4 Olori elese ni mi,
Ese mi papoju;
Nitori iku Jesu wa,
K’ o se anu fun mi.
5 Mo duro ti agbelebu,
Nko sa f’ ojiji re:
Ti Olorun t’ o po l’ anu,
O ti sanu fun mi. Amin.
