Hymn 16 Iwo Imole okan mi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Iwo Imole okan mi,
Li odo Re oru ko si,
Ki kuku aiye ma bo O,
Kuro l’ oju iranse Re.
2 Nigbat’ orun ale didun
Ba npa ipenpeju mi de,
K’ ero mi je lati simi
Lai laiya Olugbala mi.
3 Ba mi gbe l’ oro tit’ ale,
Laisi Re, emi ko le wa;
Ba mi gbe gbat’ ile ba nsu,
Laisi Re, emi ko le ku.
4 Bi otosi omo Re kan
Ba tapa s’oro Re loni,
Oluwa sise ore Re,
Ma je k’o sun ninu ese.
5 Bukun fun awon alaisan,
Pese fun awon talaka;
K’ orun alawe l’ ale yi,
Dabi orun omo titun.
6 Sure fun wa nigbat’ a ji,
K’ a to m’ ohun aiye yi se,
Titi awa o de b’ ife
T’ a o si de ijoba Re. Amin.