Hymn 159 Oluwa, gbo aroye mi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa, gbo aroye mi,
Gbo adura ikoko mi;
Lodo Re nikan, Oba mi,
L’ emi o ma wa iranwo.
2 L’ oro Iwo o gbohun mi;
L’ afemojumo ojo na;
Ni odo Re l’ emi o wo,
Si O l’ emi o gbadura.
3 Sugbon nigb’ ore- ofe Re
Ba mu mi de agbala Re,
Odo Re l’ em’ o teju mo,
Nibe ngo sin O n’ irele.
4 Je k’ awon t’ o gbekele O,
L’ ohun rara wi ayo won:
Je k’ awon t’ Iwo pamo yo,
Awon t’ o fe oruko Re.
5 Si olododo l’ Oluwa
O na owo ibukun Re;
Ojurere Re l’ enia Re
Yio si fi se asa won. Amin.