Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 153 Ko to k’ awon mimo beru Lyrics

Hymn 153 Ko to k’ awon mimo beru Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ko to k’ awon mimo beru,
Ki nwon so ’reti nu:
’Gba nwon ko reti ranwo Re,
Olugbala y’o de.

2 Nigbati Abram mu obe,
Olorun ni, “Duro” ;
Agbo ti o wa lohun ni,
Y’o dipo omo na.”

3 ’Gba Jona ri sinu omi,
Ko ro lati yo mo;
Sugbon Olorun ran eja,
T’ o gbe lo s’ ebute.

4 B’ iru ipa at’ ife yi
Ti po l’ oro Re to !
Emi ba ma k’ aniyan mi,
Le Oluwa lowo !

5 E duro de iranwo Re,
B’ o tile pe, Duro,
B’ ileri na tile fale,
Sugbon ko le pe de. Amin.

Exit mobile version