Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 150 Nigba nwon kehin si Sion Lyrics

Hymn 150 Nigba nwon kehin si Sion Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Nigba nwon kehin si Sion,
A ! opo n’iye won;
Mo seb’ Olugbala wi pe,
’Wo fe ko mi pelu ?

2 T’ emi t’ okan b’ iru eyi,
Afi b’ O di mi mu;
Nko le se kin ma fa sehin,
K’ emi si dabi won.

3 Mo mo, Iwo l’ o l’ agbara
Lati gba otosi;
Odo tani emi o lo,
Bi mo k’ ehin si O ?

4 O da mi loju papa pe,
Iwo ni Kristi na !
Eni t’ o ni emi iye,
Nipa tie je Re.

5 Ohun Re f’ isimi fun mi,
O si l’ eru mi lo;
Ife Re l’ o le mu mi yo
O si to f’ okan mi.

6 Bi ’bere yi ti dun mi to,
“Pee mi o lo bi ?”
Oluwa, ni ’gbekele Re,
Mo dahun pe “Beko.” Amin.

Exit mobile version