Hymn 140 Jesu y’o joba ni gbogbo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Jesu y’o joba ni gbogbo
Ibit’ a ba le ri orun;
’Joba Re y’o tan kakiri,
’Joba Re ki o nipekun.
2 On l’ao ma gbadura si,
Awon oba y’o pe l’Oba;
Oruko Re b’orun didun,
Y’o ba ebo oro goke.
3 Gbogbo oniruru ede,
Y’o fi ’fe Re korin didun:
Awon omode o jewo
Pe, ’bukun won t’odo Re wa.
4 ’Bukun po nibit’ On joba:
A tu awon onde sile;
Awon alare ri ’simi:
Alaini si ri ’bukun gba.
5 Ki gbogbo eda k’o dide,
Kin won f’ola fun Oba wa:
K’ Angel tun wa t’awon t’orin,
Ki gbogb’ aiye jumo gberin. Amin.