Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 139 Iyin f’Eni Mimo julo Lyrics

Hymn 139 Iyin f’Eni Mimo julo Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Iyin f’Eni Mimo julo,
Loke ati n’ile:
Oro Re gbogbo je ’yanu,
Gbogb’ ona Re daju.

2 Ogbon Olorun tip o to !
Gbat’ enia subu;
Adam keji wa s’oju ’ja,
Ati lati gbala.

3 Ogbon ife ! pe’ran ara
T’ o gbe Adam subu,
Tun b’ota ja ija otun.
K’ o ja k’o si segun

4 Ati p’ ebun t’o j’ or’ ofe
So ara di otun;
Olorun papa Tikare
J’ Olorun ninu wa.

5 Ife ’yanu ! ti Eniti
O pa ota enia,
Ninu awo awa enia
Je irora f’ enia.

6 Nikoko ninu ogba ni,
Ati lori igi,
To si ko wa lati jiya,
To ko wa lati ku.

7 Iyin f’Eni Mimo julo,
Loke ati n’ile:
Oro Re gbogbo je ’yanu,
Gbogb’ ona Re daju. Amin.

Exit mobile version