Hymn 138 ’Ranse Olorun, e ma kede Re Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 ’Ranse Olorun, e ma kede Re,
E ma k’ okiki oruko Re nla;
E gbe oruko Jesu asegun ga,
Ijoba Re l’ ogo lor’ ohun gbogbo.
2 Olodumare, O njoba loke,
O si sunmo wa, O mbe lodo wa;
Ijo nla ni y’o korin isegun Re,
O njewo pe, ti Jesu ni igbala.
3 Igbala ni t’ Olorun t’ o gunwa !
Gbogb’ aiye kigbe, e f’ola f’Omo.
Iyin Jesu ni gbogbo Angeli nke,
N’idojubole, nwon nsin Odagutan.
4 E je k’awa sin, k’a f’ iyin Re fun,
Ogo, agbara, ogbon at’ ipa,
Ola at’ ibukun, pel’ awon Angel,
Ope ti ko lopin at’ ife titi. Amin.
