Hymn 137 Wa jade larin Keferi p’ Oluwa l’ Oba Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Wa jade larin Keferi p’ Oluwa l’ Oba,
Wi jade ! Wi Jade !
Wi jade f’ orile- ede, mu ki nwon korin,
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade tiyintiyin pe, On o ma po si,
Pe, Oba nla Ologo l’ Oba Alafia;
Wi jade tayotayo, bi iji tile nja,
Pe, O joko lor’ isan omi, Oba wa titi lai.
2 Wi jade larin Keferi pe, Jesu njoba,
Wi jade ! Wi Jade !
Wi jade f’ orile- ede, mu k’ ide won ja,
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade fun awon ti nsokun, pe Jesu ye;
Wi jade f’ alare pe, O nfun ni nisimi;
Wi jade f’ elese pe, O wa lati gbala;
Wi jade fun awon ti nku pe, O ti segun iku.
3 Wi jade larin Keferi, Krist njoba loke,
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade fun keferi, Ife n’ ijoba Re.
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade lona opopo, l’ abuja ona,
Je k’o dun jakejado ni gbogbo agbaiye:
B’ iro omi pupo ni k’ iho ayo wa je,
titi gbohun- gbohun y’o fi gbe iron a de ’kangun aiye. Amin.
