Hymn 136 Krist’, ki ’joba Re de Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Krist’, ki ’joba Re de,
Ki ase Re bere;
F’ opa- irin Re fo
Gbogbo ipa ese.
2 Ijoba ife da,
Ati t’ Alafia?
Gbawo ni irira
Yio tan bi t’orun?
3 Akoko na ha da,
T’ ote yio pari,
Ika at’ ireje,
Pelu ifekufe?
4 Oluwa jo, dide,
Wa n’ nu agbara Re;
Fi ayo fun awa
Ti o nsaferi Re.
5 Eda ngan oko Re,
Koko nje Agbo Re;
Iwa ’tiju pupo
Nfihan pe ’fe tutu.
6 Okun bole sibe,
Ni ile keferi:
Dide ’Rawo oro,
Dide, mase wo mo. Amin.
