Hymn 133 E fi oju iyonu wo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 E fi oju iyonu wo
Okun ile Keferi:
Sa wo bi opolopo won
Ti njowere ’nu ese;
Okunkun bo, Okunkun bo,
Oju ile aiye wa.
2 Imole eni okunkun,
Dide, mu ibukun wa !
Imole f’ awon Keferi
Wa, pelu ’mularada;
Ki gbogb’ Oba, Ki gbogb’ Oba
Wa sinu imole na.
3 Je k’ awon Keferi ti mbo
Igi ati okuta;
Wa lati fi oribale
Fun Olorun alaye
Je k’ ogo Re, Je k’ ogo Re,
Bo gbogbo ile aiye.
4 Iwo t’ a f’ ipa gbogbo fun,
Soro na ! pa ase Re;
Je ki egbe oniwasu
Tan ’ruko Re ka kiri;
Wa pelu won, Wa pelu won,
Oluwa, titi d’ opin. Amin.