Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 129 Olorun, gbogbo araiye Lyrics

Hymn 129 Olorun, gbogbo araiye Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Olorun, gbogbo araiye
Ni eda owo Re;
Ati ni ise Re t’ a nri
Ogo didan Re ntan.

2 Sugbon ife nla Re ti ran
Ihinrere s’ aiye;
Ti nfi oro ore nla han,
T’ o ti fi se ’sura.

3 ’Gbawo n’ ihin yi yio tan
Yi gbogbo aiye ka,
Ti gbogbo eya at’ okan
Yio gbo iro na ?

4 ’Gbawo ni omo Afrika
Y’o m’ adun oro na;
At’ awon t’ o ti s’ eru pe,
Yio di omnira ?

5 ’Gbawo ni awon keferi
T’ o wa ni okunkun;
Yio joko l’ ese Jesu,
Lati ko ore Re ?

6 Oluwa bukun fun ise
Itanka oro Re;
K’ o si ko ’le iyin Re le
Ite ese t’ o wo. Amin.

Exit mobile version