Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 127 Sin awon onse Re, sin won Lyrics

Hymn 127 Sin awon onse Re, sin won Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Sin awon onse Re, sin won:
’W’Oba efufu, igbi;
A de won, O da won sile;
Nwon nlo’da eru n’ide:
Wa pelu won, Wa pelu won,
Apa Re l’o le gbala.

2 Nwon f’ile at’ore sile,
Bi ase Re Oluwa;
N’ile ati loju omi,
Je Alafehinti won;
Jo pelu won: Jo pelu won:
Si ma to won lailewu.

3 ’Biti ’se won ko m’eso wa,
To dabi ’se won j’asan;
Sunmo won l’anu Re, Jesu,
Mu ireti won duro;
Ran won lowo, Ran won lowo,
K’ itara won tun soji.

4 N’nu opolopo isoro,
K’ won gbekele O jesu;
Gbat’ ise nab a si ngbile,
Ki nwon mase gberaga;
Ma fi won ’le, Ma fi won ’le,
Titi nwon o r’oju Re.

5 Nibiti nwon o f’ayo ka
Eso irugbin aiye;
Nibiti nwon o wa titi,
Lodo Olupamo won:
Pelu ’segun, Pelu ’segun,
Nwon o ma korin Jesu. Amin.

Exit mobile version