Hymn 125 Ma sise lo, mase sare Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ma sise lo, mase sare,
Fi ayo sise Baba re;
Bayi ni Jesu se l’ aiye,
Ko ha ye, k’ awa ko se be ?
2 Ma sise lo, lojojumo,
Okunkun aiye fere de;
Mura si ’se, mase s’ ole,
Ko ba le gba okan re la.
3 Pupo pupo l’ awon t’ o ku,
Ti nwon ko n’ ireti orun;
Gbe ina ’gbagbo re, ma fi,
Ma fi si okunkun aiye.
4 Ma sise lo, ma yo pelu,
Lehin ise ’wo o simi;
O fere gbohun Jesu na,
Y’o ke tantan pe, “Emi de.” Amin.
