Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 118 Lat’ oke tutu Grinland Lyrics

Hymn 118 Lat’ oke tutu Grinland Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Lat’ oke tutu Grinland,
Lati okun India,
Nib’ odo orun Afrik,
Nsan yanrin wura won:
Lat’ opo odo gbani
Lati igbe ope
Nwon npe wa k’ a gba ’le won,
L’ ewon isina won.

2 Afefe orun didun,
Nfe jeje ni Seilon;
Bi ohun t’ a nri dara
enia l’ o buru:
Lasan lasan l’Olorun
Nt’ ebun Re gbogbo ka,
Keferi, ni ’foju won,
Nwole bo okuta.

3 Nje awa ti a moye
Nipa ogbon orun,
O to ka f’ imole du
Awon t’ o wa l’ okun ?
Igbala, A, Igbala !
Fonrere ayo na
Titi gbogbo orile
Yio mo messia.

4 Efufu, mu ’hin re lo,
Ati enyin odo;
Titi, bi okun ogo
Y’o tan yi aiye ka;
Tit’ Odagutan t’ a pa
Fun irapada wa
Yio pada wa joba,
L’ Alafia lailai. Amin.

Exit mobile version