Hymn 112 Gbo ! orin ti Jubeli Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Gbo ! orin ti Jubeli,
O dabi sisan ara;
Tabi bi kikun okun
Gbat’ igbi re ba nlu ’le
Halleluia ! Olorun
Olodumare joba:
Halleluia ! k’ oro na
Dun yi gbogbo aiye ka.
2 Halleluia ! – gbo iro,
Lati aiye de orun,
Nji orin gbogbo eda,
L’oke, nisale, yika,
Wo, Jehofa ti ete
Ida w’ako ;- o pase,
Awon ijoba aiye
Di ijoba Omo Re.
3 Y’o joba yi aiye ka,
Pelu agbara nlanla;
Y’o joba ’gbati orun,
At’ aiye ba koja lo:
Opin de: lab’ opa Re,
L’ota enia subu:
Halleluia ! Olorun
Ni gbogbo l’ohun gbogbo. Amin.