Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 110 Enyin enia Olorun Lyrics

Hymn 110 Enyin enia Olorun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Enyin enia Olorun,
Okunkun yi aiye ka;
So ihin ayo ti Jesu
Ni gbogb’ orile- ede;
Ihin ayo, Ihin ayo
Ti ’toye Olugbala.

2 Ma tiju Ihinrere Re,
Agbara Olorun ni.
N’ ilu t’ a ko wasu Jesu,
Kede ’dasile f’ onde;
Idasile, Idasile
Bi t’ awon omo Sion.

3 B’ aiye on Esu dimolu
S’ ise Olugbala wa,
Ja fun ise Re, ma foya,
Mase beru enia.
Nwon nse lasan, Nwon nse lasan,
Ise Re ko le baje.

4 ’Gbat’ ewu nla ba de sin yin;
Jesu y’o dabobo nyin;
Larin ota at’ alejo,
Jesu y’o je Ore nyin;
Itoju Re, Itoju Re
Y’o pelu nyin tit’ opin. Amin.

Exit mobile version