Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 106 Olorun Oluwa aiye Lyrics

Hymn 106 Olorun Oluwa aiye Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Olorun Oluwa aiye
’Wo t’ o ran ’rawo Re,
Lati mu awon amoye
M’ ona ibugbe Re.

2 ’Gbawo’ ni ’mole oro Re
Y’o tan yi ’lu wa ka ?
Ti aiya awon oba wa
Y’o fa si odo Re ?

3 T’ awon ijoye wa gbogbo
Yio wa juba Re;
Ti ohun ti a bi won bi
Y’o j’ asan loju won ?

4 Ile wa kun fun okunkun
Okun aiye- baiye.
Ohun inira ni fun wa,
Lati jade n’nu re.

5 Sugbon Olorun Oluwa,
Tan ’mole s’ okun wa,
K’ a le ri were ’sina wa
K’ a le ko won sile

6 ’Gbana ilu wa y’o logo
Y’o m’ ore fun O wa;
Ore t’ ise atinuwa,
At’ isi otito. Amin.

Exit mobile version