Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 104 Ese won ti da to! Lyrics

Hymn 104 Ese won ti da to! Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ese won ti da to !
Ti nduro ni Sion;
Awon t’o mu ’hin ’gbala wa,
Awon t’o f’ayo han.

2 Ohun won ti wo to !
Ihin na ti dun to !
“Sion, w’ Olorun Oba re”
B’o ti segun nihin.

3 Eti wa ti yo to !
Lati gboro ayo;
Woli, Oba, ti duro de,
Nwon wa, nwon ko si ri.

4 Oju wa ti yo to !
T’o ri ’mole orun;
Oba, Woli, nwon wa titi,
Nwon si ku, nwon ko ri.

5 Oluwa, f’ipa han;
Lori gbogbo aiye;
Ki gbogbo orile- ede
W’ Oba Olorun won. Amin.

Exit mobile version