Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 1 Ji, okan mi, ba orun ji Lyrics

Hymn 1 Ji, okan mi, ba orun ji Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

APA I

1 Ji, okan mi, ba orun ji,
Mura si ise ojo re;
Ma se ilora, ji kutu,
K’ o san gbese ebo oro.

2 Ro gbogb’ ojo t’ o fi sofo;
Bere si rere ’se loni;
Kiyes’ irin re laiye yi;
K’ o si mura d’ ojo nla ni.

3 Gba ninu imole orun,
Si tanmole na f’elomi:
Je ki ogo Olorun re
Han n’nu iwa at’ ise re.

4 Ji, gbon’ra nu, ’wo okan mi,
Yan ipo re larin Angel,
Awon tin won nkorin iyin
Ni gbogbo oru s’ Oba wa. Amin.

APA II

1 Mo ji, mo ji, ogun orun,
K’ emi l’ agbara bi tin yin;
K’ emi ba le lo ojo mi
Fun iyin Olugbala mi.

2 Ogo fun Enit’ o so mi,
T’o tu mi lara loj’ orun;
Oluwa ijo mo ba ku,
Ji mi s’ aiye ainipekun.

3 Oluwa mo tun eje je,
Tu ese ka b’ iri oro;
So akoronu mi oni,
Si f’ Emi Re kun inu mi.

4 Oro at’ ise mi oni
Ki nwon le ri bi eko Re;
K’ emi si f’ ipa mi gbogbo
Sise rere fun Ogo Re. Amin.

Exit mobile version