Hymn 86 Onigbagbo, e bu sayo ! Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Onigbagbo, e bu sayo !
Ojo nla l’ eyi fun wa;
K’ orun f’ ayo korin kikan,
K’ igbo at’ odan gberin.
E ho ! e yo ! E ho ! e yo !
Okun at’ odo gbogbo.
2 E jumo yo, gbogbo eda,
Laiye yi ati lorun;
Ki gbogbo ohun alaye
Nile loke yin Jesu.
E f’ ogo fun, E f’ ogo fun,
Oba nla t’ a bi loni !
3 Gb’ ohun nyin ga, “Omo Afrik”
Enyin iran Yoruba;
Ke ‘Hosanna !’ l’ ohun goro
Jake- jado ile wa.
K’ oba gbogbo, k’ oba gbogbo
Juba Jesu Oba wa.
4 E damuso ! e damuso !
E ho ye ! k’ e si ma yo:
Itegun esu fo wayi,
“Iru- omobinrin” de !
Halleluya ! Halleluya !
Olurapada, Oba.
5 Egb’ ohun nyin ga, Serafu,
Kerubu, leba ite;
Angeli at’ enyin mimo,
Pelu gbogbo’ ogun orun,
E ba way o ! E ba way o !
Odun idasile de.
6 Metalokan, Eni Mimo,
Baba, Olodumare,
Emi Mimo, Olutunu,
Jesu, Olurapada,
Gba iyin wa, Gba iyin wa,
’Wo nikan l’ ogo ye fun. Amin.