Hymn 468 Ore kan mbe fun omode Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ore kan mbe fun omode
Loke orun lohun;
Ore ti ki yipada,
T’ ife re ko le ku;
Ko dabi ore aiye,
Ti mbaje lododun;
Oruko Re bi ore
Wo fun nigbagbogbo.
2 Isimi kan mbe f’ omode
Loke orun lohun;
F’ awon t’ o f’ Olugbala,
Ti nke “Abba Baba:”
Isimi lowo ’yonu;
Low’ ese at’ ewu;
Nibit’ awon omode
Y’o simi titi lai.
3 Ile kan mbe fun omode,
Loke orun lohun;
Nibiti Jesu njoba,
Ile alafia!
Ko s’ ile t’o jo laiye
T’a le fi sakawe:
Ara ro ’lukuluku;
Irora na dopin.
4 Ade kan mbe fun omode
Loke orun lohun;
Enit’o ba nwo Jesu
Y’o ri ade na de:
Adet’o logo julo,
Ti y’o fi fun gbogbo
Awon ore re laiye;
Awon t’o fe nihin.
5 Orin kan mbe fun omode
Loke orun lohun;
Orin ti ko le su ni,
B’o ti wu k’a ko to!
Orin t’ awon angeli
Ko le ri ko titi;
Krist ki s’ Olugbala won,
Oba l’ o je fun won.
6 Ewu kan mbe fun omode
Loke orun lohun;
Harpu olohun didun!
Imole isegun!
Gbogbo ebun rere yi
L’ a ni ninu Jesu;
E wa, enyin omode,
Kin won le je tin yin. Amin.