Hymn 443 Sumohin, k’o gba Ara Oluwa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Sumohin, k’o gba Ara Oluwa,
K’o mu Eje mimo t’ a ta fun o.
2 Ara at’ eje na l’o gba o la,
N’ itura okan, f’ ope f’ Olorun.
3 Elebun igbala, Omo Baba,
Agbelebu Re fun wa n’ isegun.
4 A fi On rubo fun tagba tewe,
On tikare l’ Ebo, On l’ Alufa.
5 Gbogb’ ebo awon Ju laiye ‘gbani
J’ apere tin so t’ Ebo yanu yi.
6 On l’ Oludande, On ni Imole,
O nf’ Emi ran awon Tire lowo.
7 Nje, e f’okan igbagbo sunmo ‘hin,
Ki e si gba eri igbala yi.
8 On l’o nsakoso enia Re laiye,
On l’ o nf’ iye ainipekun fun wa
9 O nf’ onje orun f’awon t’ebi npa,
Omi iye fun okan npongbe
10 Onidajo wa, Olugbala wa,
Pelu wa ni ase ife Re yi. Amin.