Hymn 420 Olori Ijo t’ orun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olori Ijo t’ orun,
L’ ayo l’ a wole fun O;
K’ O to de, ijo t’ aiye,
Y’ o ma korin bi t’ orun.
A gbe okan wa s’ oke,
Ni ‘reti t’ o ni ‘bukun;
Awa kigbe, awa f’ iyin
F’ Olorun igbala wa.
2 ‘Gbat’ a wa ninu ponju,
T’ a nkona ninu ina,
Orin ife l’ awa o ko,
Ti o nmu wa sunmo O;
Awa sape, a si yo,
Ninu ojurere Re;
Ife t’ o so wa di Tire,
Y’o se wa ni Tire lai.
3 Iwo mu awon enia Re
Koja isan idanwo:
A ki o beru wahala,
T’ori O wa nitosi:
Aiye, ese, at’ Esu,
Kojuja si wa lasan
L’ agbara Re, a o segun,
A o si ko orin Mose.
4 Awa f’ igbagbo r’ ogo,
T’ o tun nfe fi wa si;
A kegan aiye tori
Ere nla iwaju wa.
Bi O ba si ka wa ye,
Awa pelu Stefen t’ o ku,
Y’o ri O bi o ti duro,
Lati pe wa lo s’ orun. Amin.