Hymn 403 Eredi irokeke yi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Eredi irokeke yi
Ti enia ti nwo koja?
’Jojumo n’ iwojopo na,
Eredi re ti nwon nse be?
Nwon dahun lohun jeje pe,
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
Nwon si tun dahun lohun jeje pe,
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
2 Tani Jesu? ese ti On
Fin mi gbogbo ilu bayi?
Ajeji Ologbon ni bi,
Ti gbogb’ enia nto lehin?
Nwon si tun dahun jeje pe,
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
Nwon si tun dahun lohun jeje pe,
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
3 Jesu, On na l’O ti koja,
Ona irora wa laiye;
’Bikibi t’ O ba de, nwon nko
Orisi arun wa ’do Re;
Afoju yo, b’o ti gbo pe,
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
Afoju yo, b’o ti gbo pw,
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
4 On si tun de! nibikibi
Ni awa si nri ’pase Re:
O nrekoja lojude wa
O wole lati ba wa gbe.
Ko ha ye k’a f’ ayo ke pe?
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
Ko ha ye k’a f’ ayo ke pe?
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
5 Ha! e wa enyin t’orun nwo!
Gba ’dariji at’ itunu:
Enyin ti e ti sako lo,
Pada, gba or’- ofe Baba;
Enyin t’a danwo, abo mbe,
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
Enyin t’a danwo, abo mbe,
“Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”
6 Sugbon b’ iwo ko ipe yi,
Ti o sig an ife nla Re,
On yio kehinda si o,
Yio si ko adura re;
“ O pe ju” n’ igbe na y’o je:
“ Jesu ti Nasaret’ ti koja.”
“ O pe ju” n’ igbe na y’o je:
“ Jesu ti Nasaret’ ti koja.” Amin.